Competition in this pair is now closed. Discussion and feedback about the competition in this language pair may now be provided by visiting the "Discussion & feedback" page for this pair. Entries may also be individually discussed by clicking the "Discuss" link next to any listed entry. Source text in English A theme of the age, at least in the developed world, is that people crave silence and can find none. The roar of traffic, the ceaseless beep of phones, digital announcements in buses and trains, TV sets blaring even in empty offices, are an endless battery and distraction. The human race is exhausting itself with noise and longs for its opposite—whether in the wilds, on the wide ocean or in some retreat dedicated to stillness and concentration. Alain Corbin, a history professor, writes from his refuge in the Sorbonne, and Erling Kagge, a Norwegian explorer, from his memories of the wastes of Antarctica, where both have tried to escape.
And yet, as Mr Corbin points out in "A History of Silence", there is probably no more noise than there used to be. Before pneumatic tyres, city streets were full of the deafening clang of metal-rimmed wheels and horseshoes on stone. Before voluntary isolation on mobile phones, buses and trains rang with conversation. Newspaper-sellers did not leave their wares in a mute pile, but advertised them at top volume, as did vendors of cherries, violets and fresh mackerel. The theatre and the opera were a chaos of huzzahs and barracking. Even in the countryside, peasants sang as they drudged. They don’t sing now.
What has changed is not so much the level of noise, which previous centuries also complained about, but the level of distraction, which occupies the space that silence might invade. There looms another paradox, because when it does invade—in the depths of a pine forest, in the naked desert, in a suddenly vacated room—it often proves unnerving rather than welcome. Dread creeps in; the ear instinctively fastens on anything, whether fire-hiss or bird call or susurrus of leaves, that will save it from this unknown emptiness. People want silence, but not that much. | Winning entries could not be determined in this language pair.There were 4 entries submitted in this pair during the submission phase. Not enough votes were submitted by peers for a winning entry to be determined.
Competition in this pair is now closed. | Kókó kan fún àkókò yìí, pàápàá ní àwọn orílẹ̀ èdè onímọ̀ ẹ̀rọ, ni pé àwọn ènìyàn ń fẹ́ ìdákẹ́jẹ́ sùgbọ́n wọn kòlerí. Ariwo ìgbòkègbodò ọkọ̀, dídún fóònù, àwọn ìkéde dígítà nínu àwọn ọkọ̀ akérò bọ́ọ̀sì àti ti ojú irin, àpotí amóhùnmáwòrán tí o ń pariwo nínu ile-isẹ́ òfìfo, àwọn wọ̀nyìí jẹ́ ìníra àti ìfọ̀kàn-kúrò. Ọmọ ènìyàn ti fi ariwo dá ara rẹ̀ lágara, èyí tí o ń mu wá ohun míìràn—bóyá nínu afẹ́fẹ́, lóri ijì òkun tàbí ní àwọn ìdákẹ́rọ́rọ́ àti ìfọ̀kànsí. Alain Corbin, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìtàn, kọ̀wé láti ibi ààbò rẹ̀ ní Sorbonne, àti Erling Kagge, asàwakíri ará Norwe, ní ìrantí rẹ̀ nípa ìjàm̀bá ti Antarctica, níbi tí àwọn méjèèjì ti gbìyànjú láti sá àsálà. Síbẹ̀si, bíì Arákùnrin Corbin ti sọ nínu "Ìtàn Ìpalọ́lọ́", pé bóyá kò tìlẹ sí aríwo bi t’àtẹ̀hìnwá. Níwájú àwọn táyà alátẹ́gùn, gbogbo òpópónà ni o kún fún ariwo gèè láti ìlurapọ̀ àwọn ríìmù ẹsẹ̀ ọkọ̀ àti bátágun ẹsẹ̀ ẹsin lóri òkúta. Sáájú ìyara sọ́tọ̀ àtinúwá lóri fóònù alágbeká, àwọn bọ́ọ̀sì àti ọkọ̀ ojú irin fún ìbára-ẹni-sọrọ̀. Àwọn olùta ìwé ìròhìn kò fi ọjà wọn sílẹ̀ nínu ọ̀gbun àìsisẹ́, sùgbọ́n wọ́n polówó wọn ní ohùn gooro, bí àwọn olùta sẹ́rì, fáólẹ́tì àti ẹja mákẹ́rẹ̀ tútù tise. Ilé ìworan àti ti ijó jẹ́ ibi ìdárúdápọ̀ ìkọlálá àti àríyànjiyàn. Pàápàá ni àwọn ìgbériko, àwọn oní kátàkárà kọrin bí wọ́n ti ń jiyàn. Wọ́n kò kọrin báyìí. Kìíse ìpele ariwo ni o ti yípadà tó bẹ̀ẹ́, èyí tí àwọn ìran ìsaajú ti sàwawí nípa rẹ̀, sùgbọ́n ìpele ìmúnilọ́kàn kúrò, èyí tí o gba ààyè tí ariwo lè wọnú rẹ̀. Ìyàlẹ́nu kan tún wà, nítorí bí o bá wà—ní àarín aginjù, ní asálẹ̀, ní ìyàrá tí a kúrò lọ́gán an—o ń bani lẹ́rù dípò gbígbà mọ́ra. Ẹ̀rù a wọlé wá; etí a là sí ohunkóhun, bóyá iná là tàbí ẹyẹ́ fọhùn tàbí rírún àwọn ewé, tí yóò gba nínu òfifo àìmọ̀ yíì. Àwọn ènìyàn ń fẹ́ ìdakẹ́, sùgbọ́n kò wọ́ pọ̀. | Entry #22493 — Discuss 0 — Variant: Not specifiednone
Voting points | 1st | 2nd | 3rd |
---|
12 | 2 x4 | 1 x2 | 2 x1 |
| Àkòrí ọ̀rọ̀ kan fún sáà yíì, bí ó tilẹ̀ jẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà nìkan, ni pé àwọn ènìyàn nlépa ìdákẹ́jẹ́ tí wọn kò sì lè rí ìkankan. Ariwo ìgbòkègbodò ọkọ̀, dídún àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ láìdẹ́kun, àwọn ìkéde orí ẹ̀rọ nínú àwọn ọkọ̀ èrò àti ọkọ̀ ojú irin, àwọn ẹ̀rọ amóhùn-máwòrán tí ó nké lala nínú àwọn yàrá tí ó ṣófo pàápàá, ni wọ́n jẹ́ ìyọlẹ́nu àti ìdíwọ́ àìlópin. Ìran ènìyàn nfi ariwo ṣe ara rẹ̀ ní wàhálà ó sì nlépa òdìkejì rẹ̀—bóyá nínú aginjù, lójú òkun tí ó tẹ́ rẹrẹ àbí ní àwọn ibi ìsinmi kan tí a fi jì fún ìdákẹ́rọ́rọ́ àti ìtẹ́tísílẹ̀. Alain Corbin, ọ̀jọ̀gbọ́n kan nínú ẹ̀kó ìtàn pípa, nkọ̀wé láti ibi ìsádi rẹ̀ ní Sorbonne, àti Erling Kagge, arìnrínàjò ọmọ Norway kan, láti inú àwọn ohun tí ó ránti nípa àwọn ìdọ̀tí tí ó wà ní Antarctica, níbi tí àwọn méjèèjì ti gbìyànjú láti sá àsálà. Àti pé síbẹ̀síbẹ̀, bí Ọ̀gbẹ́ni Corbin ti ntọ́ka síi nínú "Ìtàn Ìdákẹ́jẹ́", ó fẹ́rẹ̀ ẹ́ jẹ́ pé ariwo kò pọ̀ jù ti àtẹ̀yìnwá lọ mọ́. Kí àwọn táyà aláfẹ́fẹ́ tó dé, àwọn ìgboro ìlú kún fún ariwo àwọn irin tí ó nyí lẹ́sẹ̀ ọkọ̀ àti àwọn bàtà ẹṣin lórí òkúta, èyí tí ó lè di etí ẹni. Ṣáájú ìyara-ẹni-sọ́tọ̀ fúnra ẹni lórí àwọn ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ alágbèéká, ìtàkurọ̀sọ̀ máa ndédé dún nínú àwọn ọkọ èrò àti ọkọ ojú irin ni. Àwọn tí ó ntà ìwé ìròyìn kò kó ọjà wọn jọ ní ìdákẹ́jẹ́, ṣùgbọ́n wọ́n npolówó wọn pẹ̀lú ìkígbe-sókè, bí àwọn tí ó ntà èso àti ẹ̀ja tútù. Ilé ìwòran àti ilé ijó jẹ́ àkójọpọ̀ ariwo mo-gbà-fún-ọ àti ti ó-kù-díẹ̀-káàtó. Ní ìgbèríko pàápàá, àwọn àgbẹ̀ nkọrin bí wọ́n ti nṣiṣẹ́ kára-kára. Wọn kìí kọrin nísisìyí. Kò tíì sí ìyípadà kan gbòógì ní ipele ariwo pípa, èyí tí a ti nsọ nípa rẹ̀ láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún , ṣùgbọ́n ipele ìdíwọ́, èyí tí o gbà àlàfo tí ìdákẹ́jẹ́ ìbá ti yabò. Àtakò-ara-ẹni kan wá nrúgbó bọ̀, nítorí pé nígbà tí ó bá ya boni—nínú aginjù lọ́hún, nínú aṣálẹ̀ paraku, nínú yàrá tí a ti kó kúrò lójijì—ó sábà máa ndomi tútù síni lọ́kàn jù pé kí ó báni lára mu. Ìfòyà nyọ́ kẹ́lẹ́ wọlé; etí fi gbogbo ara là sí ohun yòówù, bóyá dídún iná àbí ìpè ẹyẹ àbí rírún àwọn ewé, ìyẹn yóò gbà á sílẹ̀ lọ́wọ́ ìdánìkanwà tí a kò mọ̀ yìí. Àwọn ènìyàn nfẹ́ ìdákẹ́jẹ́, ṣùgbọ́n kò pọ̀ tó bẹ́yẹn. | Entry #23867 — Discuss 0 — Variant: Not specifiednone
Voting points | 1st | 2nd | 3rd |
---|
8 | 1 x4 | 2 x2 | 0 |
| Kókó ohun tó gbòde kan, ó kéré tán ni abala ayé tó ti dàgbà, ni wipé àwọn èèyàn fẹ́ púpọ̀ ni ìdákẹ́rọ́rọ́ ti wọn kò si rí nkankan. Ariwo súnkẹrẹ-gbà-kẹ̀rẹ, ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ tí kò yé é dún, ìfilọ̀ ori ẹ̀rọ ninú bọ́sì àti ọkọ̀ ojú-irin, ẹ̀rọ móhùn-máwòrán tó nké tantan ninu ọfísì tó sófo, jẹ àkolùkọgbà àti ìwírèégbè tí kò lópin. Ìran èèyàn npirarẹ̀ lẹ́mi pẹ̀lú ariwo ti ó sì npòùngbẹ fun idàkejì rẹ̀ — yálà ninú igbó, lóri agbami òkun, tàbi ninú irú ipàdé ìjíròrò kan ti a yà sọ́tọ̀ fun ìdákẹ́rọ́rọ́ àti àròjinlẹ̀. Alain Corbin, ọ̀jọ̀gbọ́n ìtàn kan, kọ̀wé látibi tó sàtìpó sí ni Sorbonne, àti Erling Kagge, olùwákiri kan ni Norway látinú àwọn ìránti rẹ̀ niti àwọn ohun ìsòfò ti Antarctica, nibiti àwọn méjèjì ti gbìyànjú láti sá àsálà. Síbẹ̀síbẹ̀, gẹ́gẹ́bí Ọ̀gbẹ́ni Corbin ti tọ́kasí ninu "Ìtàn Ìdákẹ́rọ́rọ́ Kan", ó dàbí pé kò sí ariwo mọ́ ju bó ti má a nwà tẹ́lẹ̀. Ki táyà aláfẹ́fẹ́ tó dé, gbogbo ìgboro ló kún fún àwọn àgbá onírin àti àwọn pátákò ẹsin lóri òkúta ti ariwo ìrìn tó nlu ara wọn ndini léti. Sáájú ìyọ̀ọ̀da didágbé lóri ẹ̀rọ alágbèéká, bọ́sì, àti ọkọ̀ ojú-irin kún fún ọ̀rọ̀ sisọ. Àwọn atàwé-iròhin kò fi ọjà wọn silẹ̀ lójúkan, sùgbọ́n wọ́n polówó wọn lóhùn gooro, gẹ́gẹ́bi àwọn tó nta shẹ́rì, fáólẹ́tì, àti màkẹ̀rẹ́li tuntun. Gbọ̀ngàn ìseré àti òsèré jẹ́ ibi àkọlùkọgbà. Kódà ni ìgbèríko, àwọn àgbẹ̀ nkọrin bi wọn ti nrín lọ. Wọn kò kọrin mọ́ báyìí. Kiló ti yàtọ kìí se pipọ̀ ipele ariwo tó bẹ̀, èyí ti àwọn ará àtijọ́ náà ráhùn nipa rẹ̀, sùgbọ́n ipele ìrégbè, ti ó di àlàfo ti idákẹ́rọ́rọ́ kì bá gbà. Àràmàndà miràn tún fẹ ẹ̀ sún mọ́lé, nitori tó bá dé – ni ìsàlẹ igbó onígi, ninú asálẹ̀ pọ́nbélé, ninu yàrá tó sófo lójijì -— ó sábà má a njási ìfọkànbalẹ̀ dipò káábọ̀. Ẹ̀rù wọlé dé; eti nreti láti gbọ ohunkohun, bóyá dídún-iná tàbi ìpè ẹyẹ tàbi dídún ewé, ti yóò gbàá lọ́wọ́ sísófo àìmọ̀ yìí. Èèyàn nfẹ́ ìdákẹ́rọ́rọ́, sùgbọ́n kìí se pupọ̀ báyẹn. | Entry #22783 — Discuss 0 — Variant: Not specifiednone
Voting points | 1st | 2nd | 3rd |
---|
7 | 1 x4 | 1 x2 | 1 x1 |
| Ẹṣin ọ̀rọ̀ ti ìgbà ìwáṣẹ̀, ó kéré tán láwọn orílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà, ni wi pe awon eniyan a maa fẹ́ ìdákẹ́rọ́rọ́ wọ́n o sì rí. mọ́tò to n ké ramúramù, ohùn dídún fóònù láìdabọ̀, ìkéde díjítà ninu ọkọ̀ èrò bọ́ọ̀sì ati ọkọ̀ ojú irin, tẹlifíṣọ̀n tó ń ké tantan kódà nínú àwọn iléeṣẹ́ tó wà ní òfìfo, je ifipá kọlù ati ìpínyà ọkàn tí kò lópin. ìran ẹ̀dá ènìyàn máa ń fi ariwo fa rirẹ̀ tẹnutẹnu fun ara wọ́n ati yiyánhànhàn fún òdìkejì rẹ̀ - yálà nínú igbó lóríṣiríṣi, lori agbami òkun, tàbí láwọn íbi ààtò ibòji tí a yà sọ́tọ̀ fún ìtòròminimini ati ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. Alain Corbin,Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ nípa ìtàn,kọ̀wé láti ibi ìsádi rẹ̀ ni Sorbonne, ati Erling Kagge, Olùṣàwárí orílẹ̀-èdè Norway, látinú ìrírí mánigbàgbé tí o ní nipa awúrúju ilẹ̀ Antarctica, ni ibi ti àwọn méjèèjì gbìyànjú láti sá lọ. Ati síbẹ̀síbẹ̀, bi Ọ̀gbẹ́ni Corbin ti ṣe ṣàlàyé nínú "Ìtàn Ìdákẹ́jẹ́ẹ́" Ó ṣeé ṣe ko ma si ariwo mo bi i ti tele. ki táyà alafẹ́fẹ́ to de, àwọn òpópónà ìlú kun fun gbọngan-un gbọngan-un awon mẹ́táàlì ti a fi se ìgbátí sí ára àgbá tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dini létí ati pátákò ẹsẹ̀ ẹṣin lórí òkúta. ki àdádó àfínnúfíndọ̀ṣe ti ori fóònù alágbèéká to de, kọ̀ èrò bọ́ọ̀sì ati ọkọ̀ ojú irin máa ń dún pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹnu. òǹtajà ìwé ìròyìn o kii n fi oja won sile ni ìtòjọpelemọ tí ó yadi, won ma a n se ìpolówó ọjà lohun rara, bi awon ti o n ta àgbálùmọ̀, òdòdó , ẹja monkere tútù. ilé sinimá, orin aláré ati eré onítàn je ìdàrúdàpọ̀ ìró igbe àti bárékè. àní nínú àgbègbè àrọko, àwọn mẹ̀kúnnù ń kọrin bi won se n mu oògùn olóró. Won o ki n korin mo ni bayii Oun ti o yato ki i se ipele ariwo naa ni pato, eyi ti àwọn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tó ti kọjá ráhùn nípa bákan náà, sugbon ìwọ̀n ìpínyà ọkàn, ti o gba aye ti dídákẹ́ le ṣígun lọ. Irọ̀ dẹ̀dẹ̀ kàyéfì miran tun wa nibi yii, nítorí pé ti ko ba ṣígun lọ,ní àwọn apá ìsàlẹ̀ jù lọ ní àárín igbó igi ahóyaya, nínu àárín aṣálẹ̀ gbangba, nínú yàrá ti gbogbo ibẹ̀ mọ́ foo lairotele, o ma a n jáni láyà ju titẹ́wọ́ gba eniyan lo. ìbẹ̀rùbojo a wa yọ́ wọlé, eti a wa na si ohun gbogbo, boya ohun ina tí ó dún ṣì-ì-ì, tabi ìró àti orin àwọn ẹyẹ, ìró ewé tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ ni o gba a lowo inúfìfo àìmọ̀ yii. Awon eniyan a maa fe idakeroro, sugbon kii se pe kò fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ bayẹn. | Entry #22391 — Discuss 0 — Variant: Not specifiednone
Voting points | 1st | 2nd | 3rd |
---|
1 | 0 | 0 | 1 x1 |
| | | | | X Sign in to your ProZ.com account... | | | | | | ProZ.com translation contestsProZ.com translation contests offer a fun way to take a break from your normal routine while testing and honing your skills with fellow translators.
ProZ.com Translation Contests. Patent pending. |